Short Story

Ẹ̀YÌNLÁRÓ By Ọládẹ̀jọ Hammed Ọ

Written by Editor

Àgbẹ̀ paraku ni Àkànó. Ìṣẹ́ àgbẹ̀ yí náà lòun ṣe tí ó fi fẹ́ ìyàwó mẹ́rẹ́ẹ̀rin tí ó wà ní ilé rẹ̀. Oun èmọ̀ ohun àdììtú inú ọ̀rọ Àkànó niwípé, gbogbo ìyàwó ‘lé rẹ̀ ni ò lóyún àárọ̀ dalẹ́ rí. Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti sáré sókè-sódò, tí ọ̀kankan nínú wọn ò rí bí ti Séérà ni ó bá pinu láti fi ọba lée, lóbá fẹ́ ìyá Fólúsọ́. Ìbídùn ò mú oṣù àkọ́kọ́ jẹ. Eré ni, àwàdà ni,oṣù mẹ́sàán kò. Ọjọ́ tí Ìbídùn bí ọmọ rẹ̀ gan ni ó padà. Báyìí ni Ìbídùn ṣe títí tí ó ọmọ Kẹjọ fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìkúnlẹ̀ mẹ́sàán ni ìyá Fólúsọ́ kún kí Fólúsọ́ tó dúró. Àbíkú sológùn dèké ni ó jẹ́, nítorí náà ni wọ́n bá kúkú fàá f’ólúwa. Ní ọjọ́ tí wọ́n sọ Fólúsọ́ lórúkọ, ayégbọ́, ọ̀run mọ̀. Fólúsọ́ kúrò ní túnfúlù, ópa orúkọ dà, wọ́n ṣé é lámì. Báyìni Àkànó di baba ọmọ ní ọjọ́ ogbó.

Ọmọ ọdún mẹ́rin ni Fólúsọ́ wà tí ikú wọlé wá mú bàbá rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ikú ọkọ Ìbídùn, ọ̀rọ̀ bá di ọ̀rọ̀. Àwọn orogún bẹ̀rẹ̀ iná ọ̀tẹ̀ tí wọn ò dá lójú ayé ọkọ wọn. Iná ọ̀tẹ̀ yí ràn tóbẹ̀ tí Ìbídùn fi kójáde kúrò nílé fún wọn. Óní, òun ò lè jẹ́ kí wọ́n gba ọmọ pa lọ́wọ́ òhun. Mélòó n mobí. Fólúsọ́ àti ìyá rẹ̀ kó lọ ilé bàbá ìyá’rẹ̀, nílé mosú. Ìrora ilé-mosú gan wá tún fẹ́rẹ̀ẹ́ ju tilé ọkọ gan lọ,nítorí bí’gbà tí ìyà ńlá bá gbé ní sánlẹ̀, tí kékeré ń gorí ẹ̀ ni. Oríṣiríṣi ọ̀rọ kòbákùngbé ni etí Ìbídùn gbọ́. Ṣé ti yẹ̀yẹ́ wípé ó torí owó kòkò fẹ́ arúgbó tọ́nkẹ́rù kòtò ni kásọ, àbí ti ọ̀rọ ìfòyà wípé ọlọ́mọ kan ò kúrò lágàn tí wọ́n ń dá bà á. Nígbà tí àbùkù, ìwọ̀sí, àti ẹ̀gàn yí ò ṣe kó mọ́, Ìbídùn pinu láti kó jáde.

Ní ọ̀sẹ̀ tí wọ́n kó dé ilé tíwọ́n gbà gan ni àìsàn nawọ́ gán ìyá ọmọ ọdún mẹ́fà. Lórí àìsàn yìí ni gbogbo dúkìá wọn run lé. Wọ́n tà, tà, ta aṣọ ara wọn. Àìsàn yìí sọ wọ́n sí hòhò kolobo ni. Lẹ́yìn tí ìyà Fólúsọ́ ti ń yílọ, yíbọ̀ nínú ìgbèkùn àìsàn yìí ni ó bá sùn lọ́sàn án ọjọ́ kan, lóbá rí ọkọ rẹ̀ tó gbé kẹ̀hìnkẹ̀hìn, ọsẹ, pẹ̀lú omin lọ́wọ́. Ni ọkọ rẹ bá pè pé kó bẹ̀rẹ̀ kí òhun bá wẹ orí rẹ̀. Ìyàwó yìí kò kọ̀. Ó gbà. Ọkọ rẹ̀ sì wẹ orí rẹ̀. Yíyajú tí ó yajú pẹ̀lú orí tútù fún omi ni ará bá yá. Bayii ni àìsàn náà dágbére fún àgò ara rẹ̀. Pírí! Lologo ìyá Folúsọ́ bátújí.

Ní ósàn ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí àláfìa ti tóo lára ló bá bọ́sí odò, ó tọ́mi’ké,o bomi sára. Ó wẹ̀ tán. Ó kun osùn tán, lóbá ń wo ojú nínú dígí, lóbá rí ojú ara rẹ̀ tó ti hun jọ. Ni ó bá rántí orúkọ ajá bàbà rẹ̀, ẹ̀yìnláró. Ìbídùn bá kánúkò, ó ní : ìwọ̀nba èyí tókù fún òhun lókè èpè, òhun bá jọ̀sán, ọmọ òhun lókù tí òhun má gbájúmọ́. Ìbídùn wo àpo rẹ̀, ó ní bí hun ò ti ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ọmọ òun gbọ́dọ̀ nísẹ́ lọ́wọ́. Nígbà tí ó pẹ́, ni ìyá bá pe ọmọ rẹ, ó ní : Fólúsọ́ Àjàyí, mògùnrè. Mo fẹ́ kí o mọ wípé ẹnìkan tí ó jù ẹ́ lọ ní ẹni tódáyé, ọ̀run, àti gbogbo ohun tí ó bẹ nínú wọn. Ọmọ mi, Ọlọ́run nìkan ló jùẹ́lọ. Báyìí, mofẹ́ kí o lọ ronú rẹ b’osemọ. Lọ́ ròó k’ogbà lọ́kàn rẹ, ìṣẹ́ tí o bá fẹ́ kọ́. Ìbídùn ni, ówùmí kí o kàwé, ṣùgbọ́n, Ọlọhun sá má kọ ìlérí. Sá lọ ronú sí ohùn tí mo bá ẹ sọ.

Àjàyí pe ìyá rẹ̀ lárọ̀ ọjọ́ Sátidé. Óní lóru mójú ẹnì ni àró àti ọ̀dọ̀fin inú mi ríra. Wọ́n ní kí nsọ fún yín pé àwọn yọ̀nda iṣẹ́ báyà. Mo fẹ́ ma ra kòkó, èkùrọ́, àti kaṣú. Óní, ìyámi àbí kòda ni?

Ìdùnnú ni ìyárẹ̀ fi fẹ̀sì. Ó ní, ohùn èyàn ni ohùn Ọlọ́run. Tí hun ò bá ní parọ́ fún ọ, ẹ̀sì rẹ yí ṣe dédé èro ńgbà mi. Ọlọ́hun ó ṣẹ́ ni ìrọ̀rùn. Yóò sì fi àlúbàríkà si. Ṣùgbọ́n ó,Folúsọ́ ọkọ̀mi, nítorí ọjọ́ orí ẹ, ó ní láti f’ara balẹ̀ dáada.

Báyìni Fólúsọ́ bẹ̀rẹ isẹ́ kíkọ́ ọlọ́dún mẹ́fa. Ní àlàfo ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ Folúsọ́ lẹ́nu iṣẹ́, wàhálà tààràtà ni fún Folúsọ́ àti ìyá rẹ̀ torípé iṣẹ́-ilé tí fẹ́ di ti ìyá rẹ̀ nìkan. Wàhálà yí pọ̀. Kìí se tàwàdà.

Nígbà tí Folúsọ́ fi má lo ọdún márùn-ún lẹ́nu iṣẹ́, ọkùnrin tí ń dé. Òhun náà tí ń dá lọ sí ìgbèríko láti ra ọjà. Káwí, káfọ̀, ọdún mẹ́fà tipé.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan ni Folúsọ́ dédé pe ìyá rẹ̀. Ó ní, ìyá mi, ọdún mẹ́fà má tí pé e. Ó má ti kọjá oṣù kan báyìí.
Ìyá rẹ̀ míkanlẹ̀, ó ní, mo mọ̀. Kódà ọjọ́ ò tí pé tí mo ti ń múra. Ṣùgbọ́n, ó kàn wá jẹ́ wípé…
Folúsọ́ ni, ìyá mi! Ẹ má sèyọ́nu. Ní kété tí mo ti ńdá lọ ìgbèríko ni mo ti ń tiraka láti má múnú pamọ́. Ìyá mí! Mo láyọ̀ láti ṣọ funyín pé mo ti san owó iṣẹ́ àti ti ọ̀gá pẹ̀lú.
Ìyá Folúsọ́ yanu Kòle pàdé. Gbàá ló búṣẹ́kún. Nígbàtí Folúsọ́ rí pé ikun ti dàpọ̀ mọ́ omijé lẹ́rẹ̀kẹ́ ìyá rẹ̀, ó ní, ìyámi! Ẹ̀jẹ́ a dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba tólayé. Ọba tóni kí ọgbọ́n tí ẹ dá ó má jáṣọ́gbọ́n. Ẹ̀bẹ̀ ni ká má bẹ̀ẹ́ kọ́lọ́un májẹ̀ kí ọgbọ́n ọ̀hún jáságọ̀. Ìyá rẹ̀ ní àmín!

Ìyá Fólúsọ́ gbéra, ó gba agbolé ọkọ ẹ̀ lọ láti ṣe àlàyé bí iṣu ṣe kú, bọ́bẹ ṣe bẹ́ fún wọn. Nígbàtí ìyá Fólúsọ́ ó fi tú ọ̀rọ palẹ̀ tán ni bálé fi gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹ. Ó ní, kò sí àwíjàre kan, lórúkọ gbogbo ẹbí, àwọn tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ ìyá Fólúsọ́ àti Ẹlẹ́dàá ohun àti ọmọ rẹ̀. Bálé ni, bí àwọn ò tí ẹ lowo tí àwọn lè fi ran òhun àti ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó yẹ kí àwọn lè ná ìrìn ẹṣẹ̀. Bálé ni, ah! Àsé lóòótọ́ ni pé ẹ̀yìnlárò. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀, ìyá Folúsọ́ tọrọ ìyọ̀nda lọ́wọ́ olórí ẹbí pé kí wọ́n mú ọjọ́ ìgba òmìnira ọmọ wọn.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn ẹbí ọkọ ránsẹ́ pé ìyá Fólúsọ́. Wọ́n sì pinu ọjọ́ òmìnira nà.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí Fólúsọ́ ti di ọ̀gá ara rẹ̀ ni orúkọ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ròó. Nígbà tí ọdún méjì máa fi pé, Fólúsọ́ tí di ẹni igba ojú mọ̀. Ó ti di gbajúmọ̀. Ó ti di gbajú-gbajà. Ó ti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tọ̀rà-tọ̀rà kan fún ìyá rẹ̀, òhun náà sì ń lo kòrólà kékeré kan.
Báyìni ìyá Fólúsọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbénú ọlá sọlá títí tí ọlọ́jọ́ fi dé.

Lọ́jọ́ òkú ìyá Fólúsọ́, ah! Wọ́n gbọ́ lọ́run. Ọjọ́ méje ni wọ́n fi ṣe òkú ìyá Fólúsọ́. Òkú ìyá Fólúsọ́ gan ni òkú ọlọ́mọ, àṣeèsetán.

Translation
Akano is a very active farmer. He also did this farming work to marry four wives in his house. The mystery behind Akano’s life is that all the wives’ at his house never get pregnant for one day. When he had run out of water, and none of them looked like Sarah, he decided to marry the king, so he married Folu’s mother. The first month was not happy. It’s a game, it’s a joke, it’s not nine months. The day Ibidun was born, he returned. This is what Happiness did until the eighth child did. The mother-in-law bowed her head to the ground before she stopped. He was a drug addict, so they were attracted to the Lord. On the day that the name was changed, the sky was clear. The flag was removed, the name was changed, and it was marked. Akano became a father in his old age.

Fuloso was four years old when his father died. After the death of her husband, she became pregnant. Enemies start a fire that never stops. The fire was so intense that Ibidun left the house. Today, she does not allow her children to be taken away from her. Mélòó ni mobí. Foluso and his mother moved to his grandmother’s house. The pain of homelessness is even greater than that of a husband, for when a great tribulation overtakes him, he is in great distress. Excitement was heard in the audience. Is it ridiculous to say that it is because of money that the old man has to go to the ditch, or is it the fear that a child will not be left alone? When the stigma, stigma, and ridicule persisted, Gladness decided to quit.

During the week they arrived at their home, the mother of a six-year-old boy became ill. The disease destroyed all their possessions. They sell, sell, sell their clothes. The disease has left them in coma. After a long day of suffering, she fell asleep one afternoon and found her husband living for a week, with water in her hands. Then your husband asks you to take a shower. This wife does not refuse. He agreed. And her husband washed his head. A gentle breeze with a gentle breeze fills the air. Thus, the disease ceased to exist. Pírí! The mother of Folúsọ́ was baptized.

One afternoon, in a state of shock, he jumped into the river, drowned, and watered. Ó wẹ̀ tán. He was fast asleep, looking in the mirror, and seeing his woven face. Then he remembered the name of his bronze dog, a lizard. When he was angry, he said: a little bit of what was left over from the curse, if it was a day, it was a child who was not popular. Excited, he looked at his bag and said that no matter how much money he had, his son had to work. When the time came, the mother called her son and said: I want you to know that, the One who is greater than you, is the one who created the universe, the heavens, and everything in them. My son, God alone is the best. Now, I want you to think about it as a child. Contemplate this notion as you interact with your neighbors. It is a pleasure to study, but God does not reject promises. Just think of the voice I spoke to you.

Ajayi called his mother on Saturday night. Tonight I was in a trance. They asked me to tell you that they would work hard. I want to buy nuts, nuts, and cassava. Today, mom or dad?

She responded with joy. He said that the voice of man is the voice of God. If you don’t lie to me, your answer will make me think. God breaks it easily. And he will put it on. But, folks, because of your age, you have to be very calm.

So Fulos began to work for six years. In the first four years of his career, Folusso and his mother were in dire straits because their homework was only for their mother. This problem is serious. It’s not funny.

When Folúsò had not worked for five years, a man arrived. The same goes for the countryside to buy goods. Hello, six years old.

One night, Folusso suddenly called his mother. He said, “My mother, she is less than six years old.” It’s been over a month now.
His mother said, “I know.” I haven’t even been ready yet. But it just so happens that …

It’s a fluke, my mother! Don’t worry. As soon as I went to the countryside, I tried not to hide. My mother! I am happy to tell you that I have also paid my salary and that of my boss.

The mother of Foluso surprised Kole. Then he cried. When Folusso saw that his mother’s stomach was filled with tears, he said, “Mother!” We thank the King for his generosity. O king, do not let your wisdom fail you. We do not try to force the issue. His mother is amen!

The mother-in-law left and went to her husband’s house to explain how the yam had died. When Fuloso’s mother finished talking, the householder interrupted. He said that there was no excuse, on behalf of the whole family, to apologize to the mother of the Fellowship and the Creator of things and her child. At home, if they do not have enough money to support themselves and their children, they should be able to make a living. It’s home, ah! It is true that you are crazy. After much pleading, Foluso’s mother asked the head of the family for permission to celebrate her son’s independence.

A few days later, the husband’s relatives sent word to Flusso’s mother. They set a date for the release.

Six months after Paul became his master, the name began to spread. By the time he was two years old, he had become 200 years old. He has become popular. It has become popular. He had bought a luxury car for his mother, and he used a small car.
So, the mother of Folus began to honor him until the next day.

On the day of the death of Fólusò’s mother, ah! The world knows. The buria of Faluso’s mother took seven days. The corpse of the mother of Faluso was actually the corpse of a child, ready-made.

About the author

Editor

Bada Yusuf Amoo holds B.A in Literature in English from Obafemi Awolowo University, he is the publisher of thespeakingheart.com. He started the website in 2015, he has published both his works and other budding writers and poets on the website. He is a public commentators and his articles are on different websites.